![Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin](https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/d/d3/Queen_Mother_Pendant_Mask-_Iyoba_MET_DP231460.jpg/400px-Queen_Mother_Pendant_Mask-_Iyoba_MET_DP231460.jpg)
Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin jẹ́ ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n gbẹ́ lére tí ó sì jẹ́ àwòrán akọni obìrin tí a mọ̀ si ìyá wa Olorì Idia ti ọ̀rundún mẹ́rìndínlógún ṣẹ́yìn. Ọmọ rẹ̀ Esigie tí ó jẹ́ ọba ti Benin maa ń wọ́ èyí tí ó jọọ́ fún àwọn ọmọ ogun ẹ̀yìn ìya olorì. Ibojú yìí pé méjì tí ó jọ ara wọn: Ìkan wà ní Ilé ọnà ti a mọ̀ sí British Museum ní ìlú London tí ìkejì sì wà ní ilé ọnà tí a mọ̀ sí Metropolitan Museum of Art ní ìlú New York.
Àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ lórí àkọ́lé kan náà wà ní Seattle Art Museum àti Linden Museum, tí ìkan ná sì wà ní ilé ibi tí wọ́n kò gba òpò eniyan láyè láti wọ̀, gbogbo rẹ̀ ní wọ́n kó nígbà ìwádí lọ sí ìlú Benin ní ọdún 1897.
Ìbojú yìí ti di àmì ìdánimọ̀ lóde òní ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ìgbà ìpéjọ-pọ̀ kan tí a mọ̀ sí FESTAC 77 tí ó wáyé ní ọdún 1977.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ní ìrísí èyí tí ó jọ Ìbojú Ìbílẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ībòjú kékeré òhún tí kò gígùn rẹ̀ kò ju ìwòn 24cm lọ kìí ṣé fún wíwọ̀ sójú, Ọba lè wọ̀ọ́ sọ́rùn (tí ó sì maa bá mu) tàbí bi "ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí" (èyí tí ó sì maa bá ayẹyẹ tí ó fẹ́ sẹe mu). Èyí tí ó wà ní ilé ọnà Met àti èyí tí ó wà ní ilé ọnà British fẹ́ jọ ara wọn, méjèèjì ni ó jẹ́ àwòràn Olorì Idia.
Wọn dárà ìlẹ̀kẹ̀ si lórí,lọ́rùn,ègbẹ́ níwájú orí àti gbígbẹ́ èyí tí ó fàyè ọ̀nà méjì tí wọ́n lè fi ẹ̀gbà kọ́.
Lóde òní àwọn ènìyàn máa ń gbé onírú irú àworan tí ó jọ́ọ níbi ayẹyẹ láti lé ẹbọra búrúkú, ṣùgbọ́n ní bí ọrundún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn, wọ́n lè maa lòó fún ayẹyẹ ìya ọba.
Ó dàbí wípé ní bí ìbẹ̀rẹ̀ ọrúndún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọ́n gbẹ́ àwọn Ìbòjú méjèèjì, bóya ní ọdún 1520, nígbà tí Olorì Idia, ìyá ọba Oba Esigie, jẹ́ aládájọ́ ní ilé ẹjọ́ ti Benin.
Irú àwòrán yìí kò wọ́pọ̀ ní iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Benin, àti pé ipò Idia, tí iṣẹ̀ṣe àwọn Edo mọ̀ sí "obìnrin kan ṣoṣo tó lọ sógun", tí ó da yàtọ̀, tí wọ́n sí dá oyèIyoba tàbí Ìyá Olori ̀́n sílẹ̀ fun Ìwérí rẹ̀ jẹ́ ara irú irun tí wọ́n ń pè ní ukpe-okhue ("ẹnu àparò"), tí a lè rí dáadára ní àfihàn orí edẹ Olorì Idia. Ìwérí rẹ̀ tí ó rẹwà àti ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ̀ bí ìlẹ̀kẹ̀ roboto ("ọlà"), tí wọ́n fún ìya wa olorì láàfàní láti máa wọ̀, léyí tí ó jẹ́ pé olóyè ni ówà fúnwhich. Ìlẹ̀kẹ̀ pupa yìí àti aṣọ pupa, ti fìgbàkan wà fún àwọn olókìkí, tí wọ́n sì ti ri lóde òní gẹ́gẹ́ bi ara imùra ìbílẹ̀ ní Edo.
Ní iwájú orí ìbòjú méjì yìí, ìlà mẹ́rin wà níbẹ̀, tí ó sì dúro ṣangílítí sí òkè ojú kànkan, irin méjì sì ṣe àpèjúwe ilà yìí. Irin ni wọ́n fi ṣe ibi ojú rẹ̀.
Ibi funfun ìwò ẹ̀fọ̀ tí wọ́n fi ṣe ìwòjú yìí jẹ́ àpẹẹrẹ òòṣà Olokun. Bí ó ṣe rí yìí, kò wọ́n nìkan nítórí wọ́n lọ ìwo ẹfọ̀ tí ó wúlò tí ó sì ṣeétà lówó gọbọhi, ṣùgbọ́n àwọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ àpẹ́ẹrẹ òòṣà tí ó ní ṣ pẹ̀lú olá Oba Benin.
Ihò tí ó wà ní ibi oun ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àti ibi ọrùn rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí àwọn ọkùnrin Àgùdà maa ń fi ṣẹ̀ṣọ́, tí ó sì jẹ́ wípé àwòrán mọ́kànlá bẹ́ẹ̀ wà ní ilé ọnà ìbòjú tí Bìrìtìkó àti pé mẹ́tàlá wà ní ilé ọnà Met tí ó ṣe àfihàn àwọn ọkùnrin Àgùdá tí wọ́n múra bí àwọn ènìyàn dúdú. Orùn ìwòjú tí ó wà ní ilé ọnà Metropolitant (Met) jọ mọ́ èyí tí wọ́n fi àwọn ọkùnrin Àgùdà ṣẹ̀ṣọ́ rẹ̀ (ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́ díẹ̀), Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọrùn ìwòjú èyí tí ó wà ní ilé ọnà Bìrìtìkó jẹ́ èyí tí wọ́n fi igi tàbí irin gbẹ́.
Àọn Àgùdà jẹ́ oníṣòwò pẹ̀lú àwọn Benin nígbàyẹn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣàpèjúwe rẹ̀, ó jẹ́ àpẹrẹ́ àjọṣepọ̀ láàrin omi àti ilẹ̀.
John Quincy Adams (July 11, 1767 – February 23, 1848) je oloselu ara Amerika ati Aare ibe tele.
Olowe of Ise (Yoruba: Ọlọ́wẹ̀ ti Ìsẹ̀; c. 1873Àdàkọ:Spndc. 1938) ní èrò àwọn òpìtàn iṣẹ́-ọnà tí wọ́n jẹ́ Òyìnbó àti àwọn olùgbàsílẹ̀ iṣẹ́-ọnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ṣe pàtàkì jù ní sẹ́ntúrì 20 láàárín àwọn oníṣẹ́-ọnà ti àwọn ará Yorùbá tí ó jẹ́ Nàìjíríà òní, Áfíríkà . Ó jẹ́ agbẹ́gilére igi a-gbẹ́-ère àti Ọ̀gá olùdásílẹ̀ nínú àrà ìṣelọ́ṣọ̀ọ́ Áfíríkà tí a mọ̀ sí ojú-ọnà.
Ọlọ̀wẹ̀, tí wọ́n mọ̀ láti ilẹ̀ sí Olowere, ni wón bí ní Efon-Alaiye, ìlú kan tí wọ́n mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gángán ibi àṣà ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n ó gbé púpọ̀ ayé rẹ̀ ní ìgboro Ise. Wọ́n gbà á láti ìbẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ní ààfin Ọba Arinjale, Oba ti Ise. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn bóyá iṣẹ́ iṣẹ́-ọnà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọmọ ìkọ́ṣẹ́ tàbí ó dìde tààrà láti ẹ̀bùn rẹ̀ lásán. Òkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i agbẹ́gilére hàn láti bẹ̀rẹ̀ ní Ise lábẹ́ àtìlẹ́yìn Arinjale ṣáájú kí ó tó tàn ká apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Yorùbá. Wọ́n pé Olowe lọ sí Ilesa, Ikere, Akure, Idanre, Ogbagi àti àwọn ìlú Yorùbá mìíràn tí ó wà ní àárín máìlì ọgọ́ta (96.75 kilometers) láti ṣe àwọn ohun èlò ilé ńlá (gẹ́gẹ́ bí i àsè àti àgáraǹdì ) , ohun èlò ara àti ètùtù fún àwọn ìdílé olówó.
Ipò iyì Olowe gẹ́gẹ́ bí i oníṣẹ́-ọnà jẹ́ gbígbàsílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ewì alohùn Yorùbá tí a mọ̀ sí oríkì. Fún àpẹẹrẹ , èyí example tí ọ̀kan lára àwọn ìyàwó rẹ̀ kọ tí wọ́n gbàsílẹ̀ ní 1988.
Ní 1924, wọ́n ṣe àfihàn iṣẹ́-ọnà Olowe ní òke-òkun fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí wọ́n yan àṣè olókè láti ààfin ọba ní Ikere fún pàfílíọ́nù Nàìjíríà ní British Empire Exhibition ní Wembley, London. Àwọn British Museum ra iṣẹ́-ọnà yìí lẹ́yìn náà .
Christopher Uchefuna Okeke (tí wọ́n bí ní ojó ogbòn ni odún 1933 tó sì kú ní ojo karùn, osù Kinni ( Sere) odún 2016), tí ó sì tún ń jẹ́ Uche Okeke), jẹ́ ayàwòrán, agbẹ́gilére àti olùkọ́. Ó jẹ́ olùkọ́ oníṣẹ́-ọnà ní Nàìjíríà.
Wọ́n bí Christopher Uchefuna Okeke ní ojó Ogbòn, osu kerin (igbe) ni odun1933 ní ìlú Nimo, Njikoka Local Government Area ní Ìpínlẹ̀ Anámbra, ní orílè èdè Nàìjíríà. Wọ́n bi sínú ìdílé Isaac Okonkwo Okeke àti Monica Mgboye Okeke (née Okoye). Láàrin ọdún 1940 àti 1953, ó lọ sí ilé- èkó alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Peter Claver ní Kafanchan, Metropolitan College, Onitsha, àti ilé- èkó Bishop Shanahan College, ní Orlu. Lásìkò yìí, ó ti bẹ̀rẹ̀ síní fi ìfẹ́ hàn sí yíya àwòrán. Kí wọ́n tó gbà á sí Nigerian College of Arts, Science and Technology (NCAST), tó ti wá di Ahmadu Bello University, Zaria, Okeke ti ṣá̀fihàn iṣẹ́ rẹ̀ ní ìpàdé Field Society ní Jos Museum. Bákan náà ni ó kópa nínú ìṣá̀fihàn iṣẹ́-ọnà ní Nigerian Drawings and Paintings pẹ̀lú Bernard Fagg, àti ní Jos àti Kaduna pẹ̀lú ìdarapọ̀ Sir Ahmadu Bello.
Ní ọdún 1958, ó di olùdásílẹ̀ àti olùṣàkóso Asele Institute and Documentation Center, ní Nimo, Nàìjíríà.
1986–2006 Visiting professor and external examiner, University of Port Harcourt, Rivers State, Ahmadu Bello University, Zaria. Obafemi Awolowo University (formerly University of Ife).
Federal Polytechnic, Oko. Imo State University, Owerri, Nigeria.
1970–85 University of Nigeria, Nsukka, Nigeria. Positions held; Acting Head of Department, Fine and Applied Arts Department Dean Faculty of Arts Director, Institute of African Studies.
1981–82 Honorary Fellow, Department of Textile and Clothing Design, and Art History, University of Minnesota, USA (one-year sabbatical leave).
1968 Refugee Affairs Committee, Aba, Nigeria.
1964–67 Director, Mbari Art Centre, Uwani, Enugu, Nigeria.
1964–66 Artistic Director and Designer, Enugu Musical Society, Enugu, Nigeria.
1961–62 Freelance artist and Director, Cultural Centre, Kafanchan, Nigeria.
1961 Publications Artist, Federal Ministry of Information, Lagos.
1959 Founder/Director, Cultural Centre Kafanchan (now Asele Institute Nimo), Nigeria.
1958-61 Founder/First Secretary/Second President, Art Society, Nigerian College of Arts Science and Technology, Zaria, Nigeria.
1955–57 Clerk, Department of Labour, Jos and Lagos, Nigeria.
1956 Organising Assistant, Exhibition of Nigerian Painting and Drawing, Jos Museum, Jos, Nigeria.
1954–55 Designer, visual aids, St. Peter Claver's Catholic and College of Mary Immaculate Heart Practicing Schools, Kafanchan, Nigeria.
Yukio Hatoyama (鳩山由紀夫, Hatoyama Yukio, ojoibi 11 February 1947) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Japan tó di Alákòóso Àgbà orílẹ̀-èdè Japan ní Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2009 (16 September 2009). Lọ́jọ́ kejì oṣù kẹfà ọdún 2010 (2 June 2010), Hatoyama kéde pé òun kọ̀wé fiṣẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákóso Àgbà .
Dígí tàbí Díngí ìwògbè ni ohun èlò kan tí a ń lò láti fi wo àwòrán ara ẹni tí yóò sì gbé àwòrán náà wá fúni gẹ́gẹ́ a ti rí.
Lára àwọn dígí tí ó wọ́pọ̀ tí a má ń rí tàbí lò jùlọ ni panragandan (plain mirror). Èkejì ni dígí ẹlẹ́bùú (cirved mirror), wọ́n ma ń lo dígí yìí láti fi pèsè irúfẹ́ àwọn dígí mìíràn tí a lè fi wo ohun tó bá wẹ́ níye.
Paul Émile Chabas (Ọjọ́ keje Oṣù kẹta Ọdún 1869 – Ọjọ́ kẹwá Oṣù karún Ọdún1937) jẹ́ olùyàwòrán ará Faransé àti ọmọ ẹgbẹ́ Académie des Beaux-Arts.
Wọ́n bíi ní Nantes, ó sì kọ iṣẹ́ ọnà lábẹ́ William-Adolphe àti Tony Robert-Fleury. Ó kọ́kọ́ ṣe àfihàn iṣẹ́ rẹ̀ ní Salon ní ọdún 1890. Chabas gba ẹbùn Prix National ní ọdún 1899 ní Paris Salon pẹ̀lú Joyeux Ébats rẹ̀. Wọ́n fún ní ẹ̀bùn góòlú ní Exposition Universelle of 1900 àti ní ọdun 1912 tí ó gba Médaille d’honneur. Àwọn ẹka ọnà tí ó fẹ́ràn ni yíya ọoṃdébìrin tí ó wà ní ìhòho. Wọ́n gbàá ní ọ̀gá ní yiya ìhòhò ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù.
Àwọn àwòrán rẹ̀ tó lókìkí jùlọ ni , September Morn (1912), tí ó di "succès de scandale" ní United States ní oṣù karún ọdún 1913, nígbàtí Anthony Comstock, olórí New York Society for the Suppression of Vice, ṣe àtako àwòrán yìí wípé kò bójú mu. Inú bí Chabas púpọ̀ lori rògbòdìyàn tí àwòrán yìí fà. Ní igbàkan ó ṣàìfi ara hàn ní Gúúsù ti France. Ìpolongo pọ̀ lórí rẹ̀ tí wọ́n ṣe àtùnyà rẹ̀ tí wọ́n sì ń tàá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Wọ́n maa ń lo September Morn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún kitsch. Chabas kọ̀ jạ́lẹ̀ láti wọ́n mọ ẹni tí àwòrán yìí jẹ́, ọ́ kàn pèé ní "Marthe"..
Bíótilẹ̀jẹ́pé rògbòdìyàn yìí kò dáwọ́ dúró. Ní bíi ìkẹyìn ọdún 1935, àwọn ènìyàn gbọ́ ìró wípé ọmọbìrin tí ó jẹ́ àwòran yìí jẹ ẹnìkan tí ìyà ń jẹ́ tí ó n gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní U.S tí ó maa ràn-àn lọ́wọ́. Ó tún rántí bí àwọn ènìyàn kan ní U.S ti sọ wípé àwòrán yìí kò bójú mu ní bíi ogún ọdún ṣ́yìn. Chabas kọ́kọ́ lọ sí United States ní ọdún 1914 fún abala ìyàwòrán kan. Kí ó to rin ìrìnàjò yìí, ó sọ wípé oun kò fẹ́ran US, tí ó sì kọ̀ láti ta September morn fún olùtẹ̀jáde ìwé ìròyìn US, lẹ́yìn tí rògbòdìyàn nípa àwòrán yìí bẹ̀rẹ̀. Ó sọ wípé oun kò ní ìpinu láti ta àwòrán yìí, nítorí oun ni ìyàwó rẹ̀ fẹ́ràn jùlọ. Nígbà tí ó ọjà àwòran, ó dá ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wá dọ́là lée lórí tí ó sì ní ìgbàgbọ́ wípé kò sí ẹni tí ó maa ràá. Leon Mantashev, ọmọ Alexander Mantashev, gbajúgbajà elépo ni ó fẹ́ ràá tí ó sì tàá fun.
Lagos City Hall tí a mọ̀ sí Gbọ̀gán ìlú Èkó di dídásílẹ̀ ní ọdún 1900. Ó kalẹ̀ sí agbègbè àwọn ará Brazil, ní àárín èkò níbi tí ọrọ̀ ajé ti ń lọ. Ó wà ní ẹ̀gbẹ́ King's College, Lagos, St. Nicholas Hospital, Lagos àti Cathedral of the Holy Cross, Lagos.
Gbọ̀ngán ìlú yìí jẹ́ olú ilé ìjọba ìbílẹ̀ tí àwọn àgbègbè míràn sì wà fún ìṣètò ìjọbaìjọba ìbílẹ̀ ti ìletò Èkó lẹ̀yìn tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gba òmìnira. Gbọ̀ngán ìlú yìí ní àkọ́kọ́ ìjọba ìbílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó sì jẹ́ olú ilé ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Èkó níbi tí ètò ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà láti ọdún 1900. Gbọ̀ngán yìí jẹ́ ohun ìtàn, òṣèlú, tí ó sì ní ṣe pẹ̀lú àṣà Ìlú Èkó.
Pápá ìseré Onikan
Freedom Park
Queen Amina Statue
Nigerian National Museum
Lagos Trade Fair Complex
Tafawa Balewa Square
Teslim Balogun Stadium
Bar Beach, Lagos
Kalakuta Republic
MKO Abiola Statue
Apapa Amusement Park
National Temple
Owlapps.net - since 2012 - Les chouettes applications du hibou